Esekiẹli 22:19
Ezekiel 22:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu.
Ezekiel 22:19 in English
Ezekiel 22:19 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the Lord GOD says: ‘Because all of you have become dross, behold, I will gather you into Jerusalem.
Context
17Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́. 21Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.