Esekiẹli 22:20
Ezekiel 22:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.
Ezekiel 22:20 in English
Ezekiel 22:20 · Berean Standard Bible
Just as one gathers silver, copper, iron, lead, and tin into the furnace to melt with a fiery blast, so I will gather you in My anger and wrath, leave you there, and melt you.
Context
18“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́. 21Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀. 22Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.