Esekiẹli 20:46
Ezekiel 20:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù.
Ezekiel 20:46 in English
Ezekiel 20:46 · Berean Standard Bible
“Son of man, set your face toward the south,* preach against it, and prophesy against the forest of the Negev.
Context
44Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin ilé Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 45Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 46“Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù. 47Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀. 48Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.