Esekiẹli 20:47
Ezekiel 20:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.
Ezekiel 20:47 in English
Ezekiel 20:47 · Berean Standard Bible
Say to the forest of the Negev: Hear the word of the LORD! This is what the Lord GOD says: I am about to ignite in you a fire, and it will devour all your trees, both green and dry. The blazing flame will not be quenched, and by it every face from south to north will be scorched.
Context
45Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 46“Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù. 47Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀. 48Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ” 49Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Wọn ń wí fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.