Native Bible

Ezekiel 20:45 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

Ezekiel 20:45 in English

Ezekiel 20:45 · Berean Standard Bible

Now the word of the LORD came to me, saying,

Context

43Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe. 44Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin ilé Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ” 45Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 46“Ọmọ ènìyàn, dojúkọ ìhà gúúsù; wàásù lòdì sí gúúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúúsù. 47Sọ fún igbó ìhà gúúsù pé: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀, yóò sì jó olúkúlùkù igi tútù nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjò ọwọ́ iná náà ní kí yóò ṣé é pa, àti gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.