Native Bible

Ezekiel 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run.

Ezekiel 19:12 in English

Ezekiel 19:12 · Berean Standard Bible

But it was uprooted in fury, cast down to the ground, and the east wind dried up its fruit. Its strong branches were stripped off and they withered; the fire consumed them.

Context

10“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. 11Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run. 13Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi. 14Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.