Esekiẹli 19:11
Ezekiel 19:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
Ezekiel 19:11 in English
Ezekiel 19:11 · Berean Standard Bible
It had strong branches, fit for a ruler’s scepter. It towered high above the thick branches, conspicuous for its height and for its dense foliage.
Context
9Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli,
wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli. 10“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;
tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,
ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. 11Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,
ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀,
gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀. 12Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú,
á sì wọ́ ọ lulẹ̀,
afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀,
ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ
iná sì jó wọn run. 13Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀
ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.