Native Bible

Exodus 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Naili láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà.

Exodus 7:24 in English

Exodus 7:24 · Berean Standard Bible

So all the Egyptians dug around the Nile for water to drink, because they could not drink the water from the river.

Context

22Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 23Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀. 24Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Naili láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà. 25Ọjọ́ méje sì kọjá ti Olúwa ti lu odò Naili.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.