Native Bible

Exodus 7:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ.

Exodus 7:22 in English

Exodus 7:22 · Berean Standard Bible

But the magicians of Egypt did the same things by their magic arts. So Pharaoh’s heart was hardened, and he would not listen to Moses and Aaron, just as the LORD had said.

Context

20Mose àti Aaroni sí ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Ó gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ni iwájú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì lu omi odò Naili, omi odò náà sì yípadà sí ẹ̀jẹ̀. 21Ẹja inú odò Naili sì kú, odò náà ń rùn gidigidi tí ó fi jẹ́ pé àwọn ará Ejibiti kò le è mu omi inú rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ sì wà ni ibi gbogbo ni ilẹ̀ Ejibiti. 22Ṣùgbọ́n àwọn apidán ilẹ̀ Ejibiti sì ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn, ọkàn Farao sì yigbì síbẹ̀ kò sì fetí sí wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ. 23Dípò bẹ́ẹ̀, ó yíjú padà, ó sì lọ sí ààfin rẹ̀, kò sì jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí wà ni oókan àyà rẹ̀. 24Nígbà náà ni gbogbo àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ etí odò Naili láti wá omi tí wọn yóò mu, nítorí wọn kò le è mu omi tí ó wà nínú odò náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.