Native Bible

Exodus 29:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.

Exodus 29:11 in English

Exodus 29:11 · Berean Standard Bible

And you shall slaughter the bull before the LORD at the entrance to the Tent of Meeting.

Context

9ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé. “Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́. 10“Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ àjọ, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé akọ màlúù ní orí. 11Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 12Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. 13Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.