Native Bible

Exodus 29:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

Exodus 29:13 in English

Exodus 29:13 · Berean Standard Bible

Take all the fat that covers the entrails and the lobe of the liver, and both kidneys with the fat on them, and burn them on the altar.

Context

11Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 12Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. 13Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. 14Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 15“Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.