Eksodu 26:15
Exodus 26:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà.
Exodus 26:15 in English
Exodus 26:15 · Berean Standard Bible
You are to construct upright frames of acacia wood for the tabernacle.
Context
13Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì, èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó. 14Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀. 15“Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 16Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.