Native Bible

Exodus 25:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀.

Exodus 25:37 in English

Exodus 25:37 · Berean Standard Bible

Make seven lamps and set them up on the lampstand so that they illuminate the area in front of it.

Context

35Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta, ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 36Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. 37“Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀. 38Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà. 39Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.