Eksodu 25:35
Exodus 25:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta, ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀.
Exodus 25:35 in English
Exodus 25:35 · Berean Standard Bible
For the six branches that extend from the lampstand, a bud must be under the first pair of branches, a bud under the second pair, and a bud under the third pair.
Context
33Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà. 34Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 35Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta, ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 36Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. 37“Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.