Eksodu 23:14
Exodus 23:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún.
Exodus 23:14 in English
Exodus 23:14 · Berean Standard Bible
Three times a year you are to celebrate a feast to Me.
Context
12“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára. 13“Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín. 14“Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún. 15“Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.
“Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo. 16“Ṣe àjọ ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ.
“Ṣe àjọ àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó ìre oko rẹ jọ tan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.