Native Bible

Exodus 23:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

Exodus 23:12 in English

Exodus 23:12 · Berean Standard Bible

For six days you are to do your work, but on the seventh day you must cease, so that your ox and your donkey may rest and the son of your maidservant may be refreshed, as well as the foreign resident.

Context

10“Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ. 12“Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára. 13“Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín. 14“Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.