Eksodu 20:3
Exodus 20:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
Exodus 20:3 in English
Exodus 20:3 · Berean Standard Bible
You shall have no other gods before Me.*
Context
1Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé, 2“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá. 3“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi. 4Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 5Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.