Eksodu 15:2
Exodus 15:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.
Exodus 15:2 in English
Exodus 15:2 · Berean Standard Bible
The LORD is my strength and my song, and He has become my salvation. He is my God, and I will praise Him, my father’s God, and I will exalt Him.
Context
1Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa,
Èmi yóò kọrin sí Olúwa,
nítorí òun pọ̀ ní ògo.
Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún
ni ó ti sọ sínú Òkun. 2Olúwa ni agbára àti orin mi;
òun ti di Olùgbàlà mi,
òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,
Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga. 3Ológun ni Olúwa,
Olúwa ni orúkọ rẹ, 4kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀
ni ó mú wọ inú Òkun.
Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ
ni ó rì sínú Òkun Pupa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.