Native Bible

Exodus 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Exodus 14:4 in English

Exodus 14:4 · Berean Standard Bible

And I will harden * Pharaoh’s heart so that he will pursue them. But I will gain honor by means of Pharaoh and all his army, and the Egyptians will know that I am the LORD.” So this is what the Israelites did.

Context

2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni. 3Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀. 5Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.” 6Ó sì di kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.