Eksodu 14:2
Exodus 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni.
Exodus 14:2 in English
Exodus 14:2 · Berean Standard Bible
“Tell the Israelites to turn back and encamp before Pi-hahiroth, between Migdol and the sea. You are to encamp by the sea, directly opposite Baal-zephon.
Context
1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni. 3Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.