Eksodu 14:5
Exodus 14:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.”
Exodus 14:5 in English
Exodus 14:5 · Berean Standard Bible
When the king of Egypt was told that the people had fled, Pharaoh and his officials changed their minds about them and said, “What have we done? We have released Israel from serving us.”
Context
3Farao yóò ronú pé àwọn ọmọ Israẹli ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé aginjù náà ti sé wọn mọ́. 4Èmi yóò sé ọkàn Farao le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpàṣẹ Farao àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Ejibiti yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.” Àwọn Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀. 5Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Ejibiti pé àwọn ènìyàn náà ti sálọ, ọkàn Farao àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.” 6Ó sì di kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, 7ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ-ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Ejibiti, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.