Eksodu 13:19
Exodus 13:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.”
Exodus 13:19 in English
Exodus 13:19 · Berean Standard Bible
Moses took the bones of Joseph with him because Joseph had made the sons of Israel swear a solemn oath when he said, “God will surely attend to you, and then you must carry my bones with you from this place.”*
Context
17Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun. 19Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.” 20Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. 21Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.