Native Bible

Exodus 13:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun.

Exodus 13:18 in English

Exodus 13:18 · Berean Standard Bible

So God led the people around by the way of the wilderness toward the Red Sea.* And the Israelites left the land of Egypt arrayed for battle.*

Context

16Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.” 17Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun. 19Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.” 20Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.