Eksodu 13:17
Exodus 13:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.”
Exodus 13:17 in English
Exodus 13:17 · Berean Standard Bible
When Pharaoh let the people go, God did not lead them along the road through the land of the Philistines, though it was shorter. For God said, “If the people face war, they might change their minds and return to Egypt.”
Context
15Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’ 16Èyí yóò sì jẹ́ àmì ni ọwọ́ yín àti àmì ní iwájú orí yín pé Olúwa mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá.” 17Ní ìgbà tí Farao jẹ́ kí àwọn ènìyàn ó lọ, Ọlọ́run kò mú wọn tọ ojú ọ̀nà ti ó la orílẹ̀-èdè àwọn Filistini kọjá, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà kúrú. Nítorí Ọlọ́run sọ pé, “Bí wọ́n bá dojúkọ ogun, wọ́n lè yí ọkàn wọn padà kí wọ́n padà sí ilẹ̀ Ejibiti.” 18Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun. 19Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.