Native Bible

Exodus 13:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.

Exodus 13:21 in English

Exodus 13:21 · Berean Standard Bible

And the LORD went before them in a pillar of cloud to guide their way by day, and in a pillar of fire to give them light by night, so that they could travel by day or night.

Context

19Mose kó egungun Josẹfu pẹ̀lú rẹ̀ nítorí Josẹfu tí mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra. Ó ti wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò dìde fún ìrànlọ́wọ́ yín ẹ sì gbọdọ̀ kó egungun mi lọ pẹ̀lú yín kúrò níhìn-ín yìí.” 20Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti Sukkoti lọ, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu ní etí aginjù. 21Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú ọ̀wọ̀n ìkùùkuu ní ọ̀sán láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú ọ̀wọ̀n iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru. 22Ìkùùkuu náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀wọ̀n iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.