Native Bible

Esther 9:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn.

Esther 9:27 in English

Esther 9:27 · Berean Standard Bible

the Jews bound themselves to establish the custom that they and their descendants and all who join them should not fail to celebrate these two days at the appointed time each and every year, according to their regulation.

Context

25Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi. 26(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. 28A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn. 29Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.