Native Bible

Esther 9:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn,

Esther 9:26 in English

Esther 9:26 · Berean Standard Bible

Therefore these days are called Purim, from the word Pur. Because of all the instructions in this letter, and because of all they had seen and experienced,

Context

24Nítorí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, ọ̀tá gbogbo àwọn Júù, ti gbèrò sí àwọn Júù láti pa wọ́n run, ó sì ti di puri (èyí tí í ṣe ìbò) fún ìsọdahoro àti ìparun wọn. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí Esteri sọ nípa ìṣọ̀tẹ̀ náà fún ọba, ó kọ̀wé àṣẹ kan jáde pé kí ète búburú tí Hamani ti pa sí àwọn Júù kí ó padà sí orí òun fúnra rẹ̀, àti pé kí a gbé òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ kọ́ sórí igi. 26(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. 28A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.