Esteri 9:28
Esther 9:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn.
Esther 9:28 in English
Esther 9:28 · Berean Standard Bible
These days should be remembered and celebrated by every generation, family, province, and city, so that these days of Purim should not fail to be observed among the Jews, nor should the memory of them fade from their descendants.
Context
26(Nítorí náà a pe àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ní Purimu, láti ara ọ̀rọ̀ puri). Nítorí ohun gbogbo tí a kọ sínú ìwé yìí àti nítorí ohun tí wọ́n ti rí àti ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn, 27àwọn Júù fi lélẹ̀, wọ́n sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún ara wọn àti fún irú àwọn ọmọ wọn àti gbogbo àwọn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn, kò sì ní kúrò, wọn yóò sì máa pa àwọn ọjọ́ méjèèjì yìí mọ́ ní gbogbo ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ àti àkókò tí a yàn. 28A gbọdọ̀ máa ṣe ìrántí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí kí a sì máa pa wọ́n mọ́ ní ìrandíran ní gbogbo ìdílé, àti ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú. A gbọdọ̀ máa ṣe àwọn ọjọ́ Purimu wọ̀nyí ní àárín àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ di ohun ìgbàgbé láàrín irú àwọn ọmọ wọn. 29Bẹ́ẹ̀ ni Esteri ayaba, ọmọbìnrin Abihaili, pẹ̀lú Mordekai ará a Júù, kọ̀wé pẹ̀lú àṣẹ láti fi ìdí ìwé kejì nípa Purimu yìí múlẹ̀. 30Mordekai sì kọ ìwé ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn Júù, sí ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje (127) ní ilẹ̀ ọba Ahaswerusi ní ọ̀rọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.