Oniwaasu 9:4
Ecclesiastes 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!
Ecclesiastes 9:4 in English
Ecclesiastes 9:4 · Berean Standard Bible
There is hope, however, for anyone who is among the living; for even a live dog is better than a dead lion.
Context
2Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.
Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere
bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀
bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra
bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra. 3Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. 4Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ! 5Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú
ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan
wọn kò ní èrè kankan mọ́,
àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé. 6Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn,
àti ìlara wọn ti parẹ́:
láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín
nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.