Oniwaasu 9:5
Ecclesiastes 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
Ecclesiastes 9:5 in English
Ecclesiastes 9:5 · Berean Standard Bible
For the living know that they will die, but the dead know nothing. They have no further reward, because the memory of them is forgotten.
Context
3Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. 4Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ! 5Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú
ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan
wọn kò ní èrè kankan mọ́,
àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé. 6Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn,
àti ìlara wọn ti parẹ́:
láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín
nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. 7Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.