Native Bible

Ecclesiastes 3:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn.

Ecclesiastes 3:19 in English

Ecclesiastes 3:19 · Berean Standard Bible

For the fates of both men and beasts are the same: As one dies, so dies the other—they all have the same breath.* Man has no advantage over the animals, since everything is futile.

Context

17Mo wí nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ènìyàn búburú, nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.” 18Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. 19Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. 20Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí. 21Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ni?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.