Oniwaasu 3:18
Ecclesiastes 3:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí.
Ecclesiastes 3:18 in English
Ecclesiastes 3:18 · Berean Standard Bible
I said to myself, “As for the sons of men, God tests them so that they may see for themselves that they are but beasts.”
Context
16Mo sì tún rí ohun mìíràn ní
abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,
òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀. 17Mo wí nínú ọkàn mi,
“Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́
olódodo àti ènìyàn búburú,
nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,
àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.” 18Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí. 19Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín kan náà ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò sàn ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni yíyè jẹ́ fún wọn. 20Ibìkan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.