Oniwaasu 3:16
Ecclesiastes 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀.
Ecclesiastes 3:16 in English
Ecclesiastes 3:16 · Berean Standard Bible
Furthermore, I saw under the sun that in the place of judgment there is wickedness, and in the place of righteousness there is wickedness.
Context
14Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni. 15Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,
ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,
Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀. 16Mo sì tún rí ohun mìíràn ní
abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,
òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀. 17Mo wí nínú ọkàn mi,
“Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́
olódodo àti ènìyàn búburú,
nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,
àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.” 18Mo tún rò pé “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fihàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.