Oniwaasu 3:15
Ecclesiastes 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀, ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀.
Ecclesiastes 3:15 in English
Ecclesiastes 3:15 · Berean Standard Bible
What exists has already been, and what will be has already been, for God will call to account what has passed.
Context
13Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́. 14Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni. 15Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,
ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,
Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀. 16Mo sì tún rí ohun mìíràn ní
abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,
òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀. 17Mo wí nínú ọkàn mi,
“Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́
olódodo àti ènìyàn búburú,
nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,
àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.