Native Bible

Deuteronomy 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n.

Deuteronomy 9:13 in English

Deuteronomy 9:13 · Berean Standard Bible

The LORD also said to me, “I have seen this people, and they are indeed a stiff-necked people.

Context

11Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà. 12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.” 13Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n. 14Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.” 15Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá, orí òkè tí o ń yọ iná. Àwọn wàláà májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.