Deuteronomi 9:12
Deuteronomy 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
Deuteronomy 9:12 in English
Deuteronomy 9:12 · Berean Standard Bible
And the LORD said to me, “Get up and go down from here at once, for your people, whom you brought out of Egypt, have corrupted themselves. How quickly they have turned aside from the way that I commanded them! They have made for themselves a molten image.”
Context
10Olúwa fún mi ní wàláà òkúta méjì tí a fi ìka Ọlọ́run kọ. Lórí wọn ni a kọ àwọn òfin tí Ọlọ́run sọ fún un yín lórí òkè láàrín iná, ní ọjọ́ ìpéjọpọ̀ sí. 11Lópin ogójì ọ̀sán àti òru wọ̀nyí, Olúwa fún mi ní sílétì òkúta méjì, wàláà òkúta májẹ̀mú náà. 12Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìn-ín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Ejibiti ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kúrò, nínú ọ̀nà mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.” 13Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé ènìyàn ọlọ́rùn líle gbá à ni wọ́n. 14Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀jù wọ́n lọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.