Native Bible

Deuteronomy 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Deuteronomy 8:7 in English

Deuteronomy 8:7 · Berean Standard Bible

For the LORD your God is bringing you into a good land, a land of brooks and fountains and springs that flow through the valleys and hills;

Context

5Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. 6Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. 7Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin. 9Ilẹ̀ tí oúnjẹ kò ti wọ́n, kò sí ohun tí ẹ̀yin yóò ṣe aláìní, ilẹ̀ tí irin ti pọ̀ bí òkúta, ẹ̀yin sì lè wa idẹ jáde láti inú òkè rẹ̀ wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.