Deuteronomi 8:6
Deuteronomy 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀.
Deuteronomy 8:6 in English
Deuteronomy 8:6 · Berean Standard Bible
Therefore you shall keep the commandments of the LORD your God, walking in His ways and fearing Him.
Context
4Aṣọ yín kò gbó mọ́ ọn yín lọ́rùn bẹ́ẹ̀ ní ẹsẹ̀ yín kò sì wú, ní ogójì ọdún náà. 5Ẹ mọ̀ ní ọkàn an yín pé, bí baba ti ń kọ́ ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín ń kọ́ ọ yín. 6Nítorí èyí, ẹ gbọdọ̀ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́, nípa rínrìn ní ọ̀nà rẹ̀, àti bíbẹ̀rù rẹ̀. 7Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ń mú un yín bọ̀ wá sí ilẹ̀ rere ilẹ̀ tí ó kún fún odò àti ibú omi, pẹ̀lú àwọn ìsun tí ń sàn jáde láti orí òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀. 8Ilẹ̀ tí ó kún fún jéró àti ọkà barle, tí ó sì kún fún àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́, igi pomegiranate, òróró olifi àti oyin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.