Deuteronomi 5:3
Deuteronomy 5:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láààyè níbí lónìí.
Deuteronomy 5:3 in English
Deuteronomy 5:3 · Berean Standard Bible
He did not make this covenant with our fathers, but with all of us who are alive here today.
Context
1Mose sì pe gbogbo Israẹli jọ, ó sì wí pé,
Gbọ́ ìwọ Israẹli, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etí ìgbọ́ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n. 2Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Horebu. 3Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láààyè níbí lónìí. 4Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrín iná lórí òkè. 5(Ní ìgbà yìí, mo wà láàrín ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè.)
Ó sì wí pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.