Deuteronomi 33:22
Deuteronomy 33:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ti Dani ó wí pé, “Ọmọ kìnnìún ni Dani, tí ń fò láti Baṣani wá.”
Deuteronomy 33:22 in English
Deuteronomy 33:22 · Berean Standard Bible
Concerning Dan he said: “Dan is a lion’s cub, leaping out of Bashan.”
Context
20Ní ti Gadi ó wí pé,
“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
ó sì fa apá ya, àní àtàrí. 21Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
ìpín olórí ni a sì fi fún un.
Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,
àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.” 22Ní ti Dani ó wí pé,
“Ọmọ kìnnìún ni Dani,
tí ń fò láti Baṣani wá.” 23Ní ti Naftali ó wí pé,
“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run
àti ìbùkún Olúwa;
yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.” 24Ní ti Aṣeri ó wí pé,
“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;
jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀
kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.