Deuteronomi 33:15
Deuteronomy 33:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
Deuteronomy 33:15 in English
Deuteronomy 33:15 · Berean Standard Bible
with the best of the ancient mountains and the bounty of the everlasting hills,
Context
13Ní ti Josẹfu ó wí pé,
“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,
fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀; 14àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù; 15pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé; 16Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀. 17Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
pàápàá títí dé òpin ayé.
Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,
àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.