Deuteronomi 33:14
Deuteronomy 33:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
Deuteronomy 33:14 in English
Deuteronomy 33:14 · Berean Standard Bible
with the bountiful harvest from the sun and the abundant yield of the seasons,
Context
12Ní ti Benjamini ó wí pé,
“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,
òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,
ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.” 13Ní ti Josẹfu ó wí pé,
“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,
fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀; 14àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù; 15pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé; 16Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.