Native Bible

Deuteronomy 32:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́ èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?

Deuteronomy 32:34 in English

Deuteronomy 32:34 · Berean Standard Bible

“Have I not stored up these things, sealed up within My vaults?

Context

32Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra. Èso àjàrà wọn kún fún oró, ìdì wọn korò. 33Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni, àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀. 34“Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́ èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi? 35Ti èmi ni láti gbẹ̀san. Èmi yóò san án fún wọn ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ; ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.” 36Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.