Deuteronomi 32:27
Deuteronomy 32:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá, kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni; kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
Deuteronomy 32:27 in English
Deuteronomy 32:27 · Berean Standard Bible
if I had not dreaded the taunt of the enemy, lest their adversaries misunderstand and say: ‘Our own hand has prevailed; it was not the LORD who did all this.’”
Context
25Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.
Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú. 26Mo ní èmi yóò tú wọn ká
èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn, 27nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má
ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;
kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ” 28Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn. 29Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.