Deuteronomi 32:25
Deuteronomy 32:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù, ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá. Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú.
Deuteronomy 32:25 in English
Deuteronomy 32:25 · Berean Standard Bible
Outside, the sword will take their children, and inside, terror will strike the young man and the young woman, the infant and the gray-haired man.
Context
23“Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lórí
èmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára. 24Èmi yóò mú wọn gbẹ,
ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.
Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀. 25Idà ní òde, àti ẹ̀rù nínú ìyẹ̀wù,
ni yóò run ọmọkùnrin àti wúńdíá.
Ọmọ ẹnu ọmú àti arúgbó eléwú irun pẹ̀lú. 26Mo ní èmi yóò tú wọn ká
èmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúrò nínú àwọn ènìyàn, 27nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀tá,
kí àwọn ọ̀tá a wọn kí ó má
ba à wí pé, ‘Ọwọ́ wa lékè ni;
kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.