Native Bible

Deuteronomy 23:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi.

Deuteronomy 23:22 in English

Deuteronomy 23:22 · Berean Standard Bible

But if you refrain from making a vow, you will not be guilty of sin.

Context

20Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní. 21Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 22Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi. 23Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ. 24Bí ìwọ bá wọ inú ọgbà àjàrà aládùúgbò rẹ, o lè jẹ gbogbo èso àjàrà tí o bá fẹ́, ṣùgbọ́n má ṣe fi nǹkan kan sínú agbọ̀n rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.