Deuteronomi 23:21
Deuteronomy 23:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.
Deuteronomy 23:21 in English
Deuteronomy 23:21 · Berean Standard Bible
If you make a vow to the LORD your God, do not be slow to keep it, because He will surely require it of you, and you will be guilty of sin.
Context
19Ìwọ kò gbọdọ̀ ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá. 20Ìwọ lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Israẹli, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní. 21Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, má ṣe lọ́ra láti san án, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, o sì máa jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. 22Ṣùgbọ́n tí o bá fàsẹ́yìn láti jẹ́ ẹ̀jẹ́, o kò ní jẹ̀bi. 23Rí i dájú pé o ṣe ohunkóhun tí o bá ti ètè rẹ jáde, nítorí pé ìwọ fi tinútinú rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ẹnu ara rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.