Native Bible

Deuteronomy 21:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í.

Deuteronomy 21:14 in English

Deuteronomy 21:14 · Berean Standard Bible

And if you are not pleased with her, you are to let her go wherever she wishes. But you must not sell her for money or treat her as a slave, since you have dishonored her.

Context

12Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, 13kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ. 14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í. 15Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn. 16Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.