Deuteronomi 21:16
Deuteronomy 21:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn.
Deuteronomy 21:16 in English
Deuteronomy 21:16 · Berean Standard Bible
when that man assigns his inheritance to his sons he must not appoint the son of the beloved wife as the firstborn over the son of the unloved wife.
Context
14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í. 15Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn. 16Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn. 17Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀. 18Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.