Deuteronomi 21:12
Deuteronomy 21:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀,
Deuteronomy 21:12 in English
Deuteronomy 21:12 · Berean Standard Bible
then you shall bring her into your house. She must shave her head, trim her nails,
Context
10Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá rẹ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbèkùn, 11tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbèkùn, tí o sì ní ìfẹ́ sí i, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ. 12Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, 13kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ. 14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.